Ààrẹ CAF tẹ́lẹ̀rí kú lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 9, 2024

Ààrẹ CAF tẹ́lẹ̀rí kú lójijì


Aarẹ tẹlẹri fun ajọ to n ṣakoso ere bọọlu nilẹ adulawọ, Confederation of African Football (CAF), Issa Hayatou ti jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin (77).

Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii ni Hayatou dagbere faye niluu Paris, lẹyin aisan to kọlu.

Awọn alakoso Concord ti orileede Cameroon lo gbe iroyin ọhun sita.

Aarin ọdun 1988 si oṣu kẹta, ọdun 2017 ni Hayatou fi jẹ aarẹ fun ajọ CAF, to si gbe ijọba silẹ fun Ahmad Ahmad ti Malagasy.

Hayatou tun jẹ aarẹ fidihẹ fẹgbẹ FIFA laarin oṣu kẹwaa, ọdun 2015 si oṣu keji, ọdun 2016, lẹyin ti wọn jawe lọ rọkunle fun Sepp Blatter nigba naa.

Oloogbe yii lo ṣakoso eto idibo to gbe alakoso FIFA, Gianni Infantino wọle sipo.

Agbẹnusọ Cameroon Concord ninu ọrọ rẹ, sọ pe “A ti padanu adari to fi ipa rere lelẹ, ọkunrin to ti fi aye rẹ jin fun idagbasoke ere bọọlu nilẹ Afrika.
“Ipa rere to fi silẹ ni yoo tubọ maa ṣe atọna wa lati mu ilọsiwaju ba eto ere idaraya nilẹ Afrika.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI