A kò lè mú gbogbo àwọn ọ̀daràn tán lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo – Adéjọbí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 10, 2024

A kò lè mú gbogbo àwọn ọ̀daràn tán lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo – Adéjọbí


Agbẹnusọ agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lorileede Naijiria, Olumuyiwa Adejọbi ti jẹ ko di mimọ pe ko ṣee ṣe fun ileeṣẹ ọlọpaa lati mu gbogbo ọdaran tan lẹẹkan ṣoṣo.

O sọ pe diẹdiẹ ni ọwọ yoo maa tẹ gbogbo ọdaran, to fi mọ awọn amookunṣeka titi digba ti iwa ọdaran yoo fi dohun igbagbe.

Adejọbi lo sọrọ naa loju opo ‘X’ lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja, to si ni ileeṣẹ ọlọpaa n gbiyanju agbara wọn lati ri ọwọ iwa ibajẹ bolẹ.

Ninu ọrọ Adejọbi, o ṣalaye:
“A ko le rọwọ to gbogbo ọdaran tan lẹẹkan ṣoṣo. Sibẹ, ẹ gbọdọ maa yin wa fun awọn diẹ ti a ti fi ọwọ ofin mu. Ojoojumọ la n rọwọ to wọn, ni ọpọ yanturu.

“Ileeṣẹ ologun ati ọlọpaa n gbiyanju agbara ati akitiyan wọn. Ẹ gbọdọ maa ri ipa ati akitiyan ileeṣẹ agbofinro, ki ẹ si maa gboriyin fun wa.

“A ni lati maa ṣiṣẹ lori ajọṣepọ nipa idasi ẹnikọọkan lati gbogun ti iwa aisi eto aabo ati oniruuru iwa ọdaran ni Naijiria.

“Ohun kan to daju ni pe ko si ọdaran to maa lọ lai jiya. Ẹ ṣeun.”


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI