Wọn dibo yan Ọgbẹni Odulatẹ gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ to yọranti nipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 26, 2024

Wọn dibo yan Ọgbẹni Odulatẹ gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ to yọranti nipinlẹ Ogun


Ọgbẹni Afọlabi Odulatẹ to jẹ alaga ijọba ibilẹ Ṣagamu nipinlẹ Ogun ti sọ ọ di mimọ pe oun yoo tẹsiwaju lati maa ṣe ifẹ araalu titi de ibi to ni apẹẹrẹ.

Ọnarebu Odulatẹ sọ pe ifẹ araalu to jẹ oun logun, toun si n ṣe ohun ti wọn n fẹ, lo fa a ti gbogbo ilu fi nífẹẹ oun.

Odulatẹ lo sọrọ yii l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2024 nibi ti ileeṣẹ Amebo Communications ti fi aami ẹyẹ da a lọla gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ to ṣe daadaa julọ nipinlẹ Ogun ni saa yii.

Odulatẹ sọ pe oun mọ riri bi awọn ọmọ ipinlẹ Ogun ṣe dibo yan oun ninu eto idibo to waye lori ayelujara, to si jẹ pe oun ni wọn mu.


https://youtu.be/X3xFAoc_XSA?si=-D120CQRjYNl344I

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI