Tinubu yoo fi iwe abadofin owo oṣu tuntun ranṣẹ sile igbimọ aṣofin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 15, 2024

Tinubu yoo fi iwe abadofin owo oṣu tuntun ranṣẹ sile igbimọ aṣofin



Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe oun yoo fi iwe abadofin owo oṣu tuntun ranṣẹ sile igbimọ aṣofin agba orile-ede Naijiria lati buwọ lu.

Ọsẹ to n bọ ni Aarẹ Tinubu sọ pe oun yoo fi iwe naa ranṣẹ sile aṣofin.

Eyi la gbọ pe yoo waye lẹyin ti aarẹ ba pari ipade pẹlu awọn olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ Naijiria tii ṣe NLC ati TUC.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni aarẹ ba apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe ipade lati jiroro lori iye ti owo oṣu tuntun yoo jẹ.

Ẹgbẹrun lọna igba le laadọta (₦250,000) naira ni ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere fun, ṣugbọn ti igbimọ aarẹ lori ọrọ owo oṣu sọ pe ijọba ko le san ju ẹgbẹrun mejilelọgọta naira lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI