Ẹ wa gbọ aṣiri bi ogbontarigi onkọrin nni, Onyeka Onwenu ṣe jade laye lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 31, 2024

Ẹ wa gbọ aṣiri bi ogbontarigi onkọrin nni, Onyeka Onwenu ṣe jade laye lojiji


Ogbontarigi onkọrin ọmọ ilẹ Naijiria nni, Onyeka Onwenu ti jade laye lẹni ọdun mejilelaadọrin.
 
Alẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja yii ni Onwenu to tun jẹ agba oṣere nigba aye rẹ ki aye pe o digboṣe ni ọsibitu Reddington to wa nipinlẹ Eko.
 
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ sọ pe agba onkọrin naa yọ ṣubu ni kete to fi orin da awọn alejo laraya nibi ayẹyẹ ọjọ ibi Arabinrin Stella Okoli.
 
Loju ẹsẹ to yọ ṣubu la gbọ pe awọn to wa nibẹ ti sare gbe e, ti wọn si sa gbogbo ipa wọn lati doola ẹmi rẹ.
 
Igba ti wọn sọ pe ọrọ fẹẹ yiwọ, ni wọn sare gbe e lọ si ọsibitu Raddington naa lati doola ẹmi rẹ.
 
Ọkan lara awọn to wa nibi ayẹyẹ ọjọ ibi naa, ẹni to ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn akọroyin sọ pe iyalẹnu nla lo jẹ fun wọn.
 

Ẹni naa sọ pe kayeefi nla lo jẹ pe Onweka to ṣẹṣẹ kọrin tan lo yọ ṣubu nibi eto ayẹyẹ ọjọ ibi naa.
 
O lo ṣe oun laanu wi pe ẹpa ko boro mọ nigba ti wọn yoo fi gbe e de ile iwosan naa, nibi to pada dakẹ si.
 
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akoj]opọ iroyin yii ni awọn mọlẹbi oloogbe naa ko tii sọrọ, sibẹ ọpọ awọn eeyan lo ti n kẹdun iku agba onkọrin ati oṣere naa.
 
Awọn orin maingbagbe rẹ pọ yanturu bii 'In The Morning Light', ati 'Dancing In The Sun'.
 
Bẹẹ lo tun kopa ninu awọn sinima bii Half of a Yellow Sun, Lions Heart, ati awọn miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI