Iṣẹ́ ọlọ́pàá ló dára jùlọ làgbáyé, ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn fí n gbàdúrà fún wa - Ẹgbẹ́tókun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 18, 2024

Iṣẹ́ ọlọ́pàá ló dára jùlọ làgbáyé, ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn fí n gbàdúrà fún wa - Ẹgbẹ́tókun


Ọga ọlọpaa lorileede Naijiria, Kayọde Ẹgbẹtokun ti sọ pe ko si iṣẹ meji to dara julọ lagbaye, to kọja iṣẹ ọlọpaa.

Ẹgbẹtokun ni ojoojumọ ni awọn eeyan kaakiri fi n gbadura fun wọn lori awọn iṣẹ ti wọn n se.

Ọga ọlọpaa naa lo sọrọ yii nibi abẹwo ọlọjọ meji to ṣe lọ si ipinlẹ Ẹdo.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Iṣẹ ọlọpaa ni iṣẹ ti o maa ṣe e ti awọn eeyan yoo gbadura fun ẹ. Bakan naa lo tun jẹ iṣẹ ti wọn yoo tun maa ṣe idakeji adura fun ẹ.

"Fun idi eyi, iwọ ọlọpaa lo maa ṣe ipinnu iru eyi ti o fẹ ninu adura ati idakeji rẹ."

O wa gba gbogbo awọn ọlọpaa lamọran lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bo ti tọ, ati bo ti yẹ nipa otitọ ati iwa ọmọluwabi si araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI