Ileeṣẹ ADRON Homes mu ayipada ọtun ba agbegbe Ṣimawa nipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 26, 2024

Ileeṣẹ ADRON Homes mu ayipada ọtun ba agbegbe Ṣimawa nipinlẹ Ogun


Bi wọn ba n darukọ agbegbe ti ọlaju tete wọ kaakiri ipinlẹ Ogun lonii, agbegbe kan ti wọn n pe ni Ṣimawa nijọba ibilẹ Ṣagamu wa lara marun-un akọkọ.

Ko si sohun to fa a, bi ko ṣe ọna ti ileeṣẹ Adron Homes gba lati gbe eto ile gbigbe kalẹ nibẹ, to si mu ki gbogbo eeyan sọ agbegbe naa di aayo.

Pupọ awọn to n gbe lagbegbe yii ni wọn n fi idupẹ wọn han si awọn alakoso ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited ti Aarẹ Adetọla EmmanuelKing jẹ alakoso ati oludari rẹ.

Yatọ si pe agbegbe ọhun jẹ ibi ifọkanbalẹ lati gbe, bẹẹ lo tun jẹ agbegbe ti irọrun wa lati ṣiṣẹ oojọ, paapaa nipa dida iṣẹ silẹ.

Awọn ileeṣẹ nla-nla ni wọn ti gbẹrẹgẹjigẹ lagbegbe Ṣimawa ti a n sọ yii, koda ti awọn ijọba gan-an n sọ pe iyalẹnu lo n jẹ fun wọn bi agbegbe ọhun ṣe tete ni idagbasoke.

Nipa ti opopona, ina ẹlẹntiriki, omi igbalode ati oniruuru awọn ohun amuṣọrọ, Ṣimawa jẹ ọkan lara awọn to n gbadun awọn nnkan wọnyi.

Ileeṣẹ Adron Homes ti ta awọn ile igbalode ti a mọ si Estate mẹrin ọtọọtọ laarin ọdun mẹwaa sẹyin, ti wọn si tun ti n ta marun-un bayii.

Lara wọn ni

• Treasure Park and Gardens Estate Phase 2  (City of David)
• Treasure Park and Gardens Estate Phase 3 (Capetown)
• Treasure Park and Gardens Estate Phase 3 Extention (Jerusalem City)
• Treasure Park and Gardens Estate Phase 4 (Jerusalem Extention)
• Treasure Park and Gardens Estate Phase 5 (City of God)

Gbogbo awọn ile gbigbe igbalode yii lo rọrun lati ra pẹlu owo ti ko ga ni lara rara, koda, anfaani tun wa lati maa san owo diẹdiẹ.

Bi ẹyin naa ba fẹẹ di onile lori lai laagun jinna, ẹ tete kan si ileeṣẹ Adron Homes to wa lagbegbe yin nibikibi lorileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI