Fafoluyi, amugbalẹgbẹ Gomina AbdulRazaq gba aami ẹyẹ tuntun ninu ilana iṣẹ akọroyin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 31, 2024

Fafoluyi, amugbalẹgbẹ Gomina AbdulRazaq gba aami ẹyẹ tuntun ninu ilana iṣẹ akọroyin


Amugbalẹgbẹ pataki lori eto iroyin ayelujara fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara, Ọlayinka Micheal Fafoluyi ti gba aami ẹyẹ nile ẹkọ akọroyin to wa nipinlẹ Eko.
 
Ọlayinka ti ọpọ awọ ololufẹ rẹ mọ si Solace lo ṣẹṣẹ gba iwe ẹri ti Post Graduate Diploma nilana iṣẹ akọroyin nile ẹkọ giga ti Nigerian Institute of Journalism (NIJ) to wa lagbegbe Ọgba, ipinlẹ Eko.

AWIKONKO gbọ pe Solace to tun jẹ akẹkọọjade ni fasiti tiluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara wa lara awọn to ṣe daadaa julọ (Upper Credit) ni ile-ẹkọ giga NIJ.

Nigba to n sọrọ, Fafoluyi sọ pe lati le tun ni imọ kikun nipa eto iṣẹ akọroyin lo fa a, toun fi lọ kẹkọọ siwaju sii ni NIJ.
 
O loun fẹẹ di ogbontarigi ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu iṣẹ akọroyin ati igbohunsafẹfẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI