Gbajugbaja onta-ilẹ nni, Oloye Rafiu Oseni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ẹlẹlẹ ti rawọ ẹbẹ si awọn ọdọ Naijiria lati ma ṣe fa wahala lasiko eto ifẹhonuhan ti wọn gbero lati ṣe lọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun ti a wa yii.
Ẹlẹlẹ sọ pe Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu n gbiyanju agbara rẹ lati mu Naijiria tẹsiwaju kuro ninu iṣẹ ati oṣi to n ba araalu finra, ṣugbọn to sọ pe omi lo pọ ju ọka lọ.
Oloye Oseni lo sọrọ yii niluu Mowe, ipinlẹ Ogun lonii, ọjọ Iṣẹgun, lasiko to n ba awọn ara agbegbe Owode, Ọfada ati agbegbe rẹ ṣe ipade lori alaafia orileede Naijiria.
Bi ẹ ko ba gbagbe, pupọ awọn ọdọ Naijiria, paapaa awọn ti ebi n pa ni wọn sọ pe awọn yoo bẹrẹ ifẹhonuhan lọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 2024.
Wọn ni awọn n fẹ ayipada rere ninu eto iṣejọba Naijiria, ati paapaa ki opin de ba gbogbo iwa jẹgudujẹra ati ailaanu ti awọn oloṣelu n hu.
Oloye Oseni to jẹ Apagunpọtẹ ilu Igbein ni tile-toko sọ pe ki awọn odo
Elele pe fun ipade alaafia lasiko iwode ati ifehonu han ni Mowe ati agbegbe re
Apagunpọtẹ yii sọ pe Aarẹ Tinubu ni erongba rere fun ọmọ Naijiria, to si n sa gbogbo ipa ati akitiyan yan rẹ lati rii pe araalu gbadun mudunmudun eto iṣejọba awa-ara-wa.
Bo tilẹ jẹ pe o ni niṣe lọrọ aarẹ dabi adiẹ to n laagun, ṣugbọn ti iyẹ ara rẹ ko jẹ k'awọn eeyan mọ, sibẹ o ni ki wọn tubọ ṣe suuru.
O ni ki awọn to ba fẹẹ jade fun iwọde ṣee ni ilana ọmọluwabi, ki wọn ma si ṣe fa wahala tabi ba dukia ijọba ati ti araalu jẹ.
Lara awọn to wa nibẹ ni awọn adari agbegbe, awọn olori ẹsin, to fi mọ awọn aṣoju ileeṣẹ agbofinro ati eleto aabo.
Bakan naa lo rọ gbogbo ẹya patapata lati gba ifẹ ati iṣọkan laaye lasiko ifẹhonuhan wọn.
No comments:
Post a Comment