Aarẹ EmmanuelKing ba iyawo gomina ipinlẹ Ogun, Bamidele Abiọdun yọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 18, 2024

Aarẹ EmmanuelKing ba iyawo gomina ipinlẹ Ogun, Bamidele Abiọdun yọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi


Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing ti ba iyawo Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun, Arabinrin Bamidele Abiọdun yọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹtadinlọgọta.

Lonii, ọjọ kejidinlogun, oṣu keje, ọdun 2024 ni Arabinrin Bamidele Abiọdun n ṣayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, ti gbogbo aye si n kii ku oriire.

Aarẹ EmmanuelKing ninu atẹjade ikini to fi ranṣẹ si Arabinrin Bamidele Abiọdun, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bi obinrin rere lọdẹdẹ ọkọ.

O ni ipa rere ti Arabinrin Abiọdun n ko lawujọ, paapaa lawujọ awọn ọmọde ati obinein ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.

O wa gbadura alaafiaa ati ẹmi gigun fun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI