Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti sọ pe adojukọ nla ni iṣakoso ọdun marun-un yii jẹ foun, ati pe iriri aladun toun ko le gbagbe ni igbesi aye oun ni.
Dapọ Abiọdun lo sọ eyi di mimọ nibi eto isin idupẹ ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹrinlelọgọta ati ọdun marun-un to ti wa lori ipo gẹgẹ bi gomina, eyi to waye nile ijọsin ti ijọba to wa ni Oke-Igbein niluu Abẹokuta.
Nibẹ lo ti sọ pe igbagbọ oun ninu Ọlọrun lo mu iṣẹgun toun n gbero wa, ti ohun gbogbo si n ṣiṣẹ fun rere.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
"Igbesẹ ti mo gba lati di gomina jẹ eyi ti kii ṣe bo ti n ṣẹlẹ, eyi ni bi ẹni ti mo gba ipo lọwọ rẹ, ẹni ti a tun jọ wa ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa tun n ba mi ja, to si n polongo ibo fun ẹlomiran ninu ẹgbẹ oṣelu miran
"Maa si wa jokoo lati maa beere lọwọ ara mi pe 'Ọlọrun Baba, eyi kii ṣe bo ṣe yẹ ko ri, ki lo de ti mo fi gbọdọ la eyi kọja ki n to de ipo?' nigba naa ni maa tun da ara mi lohun wi pe nitori Ọlọrun fẹẹ gba ogo yẹn ni.
"Ọdun marun-un sẹyin ninu iṣakoso mi gẹgẹ bii gomina jẹ awọn igba iriri to dun fun mi. Iji nla ni, ipenija nla ni. Eyi to ṣe pataki julọ ni pe ninu ohun gbogbo wọnyi, Ọlọrun ti fun wa ni iṣẹgun."
No comments:
Post a Comment