Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti buwọ lu iṣẹ akanṣe opopona tuntun ti kilomita jẹ kilomita marundinlaadọrun (84.7km).
Eyii ni lati mu idagbasoke ba eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin labẹ aburada ti wọn pe ni Kwara State Rural Access and Agricultural Marketing Project (RAAMP).
Biliọnu mẹsan le lọọdunrun (₦9.3b) naira la gbọ pe ijọba yoo na lori awọn opopona tuntun wọnyi, lati le mu ki igbokegbodo ọkọ tẹsiwaju kaakiri ipinlẹ naa.
Alakoso RAAMP, Onimọ-ẹrọ Isaac Kolo lo sọ eyi di mimọ niluu Ilọrin laipẹ yii lasiko to n buwọ lu iwe adehun laarin ijọba ati awọn agbaṣẹṣe ti iṣẹ naa ja mọ lọwọ.
Kolo, ẹni to ṣapejuwe iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, o ni ọrẹ araalu to n fẹ alaafia ati ẹmi gigun fun awọn eeyan ni.
O ni igbagbọ ati aridaju ti wa pe iṣoro igbokegbodo ọkọ to ja geere yoo di ohun igbagbe laipẹ, paapaa lawọn igberiko to wa kaakiri ipinlẹ naa.
Awọn agbaṣẹṣe ọhun ni RAFALI Nig Ltd, NBHH Nig Ltd, Fik Contracting Engineering Ltd, Tundis Nig Ltd, ati Heriprom Engineering Ltd.
Lara awọn opopona ti wọn yoo ṣe ni atunṣe awọno opopona to tin dẹnu kọlẹ lawọn igberiko to jẹ kilomita mẹrindinlaadọrin ataabọ (66.5Km) ni ijọba ibilẹ Asa, Ilorin West/East, Oyun, ati Edu.
Awọn miran ni Mondala-Yowere-Agbonna 12.485 Km; Gerewu-Eiyekorin-Okolowo Express 3.069 Km; Panada-Oloro, 5.428 Km; Inaja-Alaro-Inaja maliki, 6.215 Km, Ijagbo-Aperun-Adeleke-Igbawere 6.85 Km; Kpandarako-Ginda-Kusomunu-Kachitako, Tsakpata Lealea-Gulufu-Bacita, 22.89 Km; ati Lafiagi-Effagi-Putata, 9.525 Km; ti apapọ rẹ jẹ 66.46 Km.
No comments:
Post a Comment