Aarẹ orileede Liberia, Joseph Boakai ti gbe oṣuba kare fun Olu tilu Orile-Ilawọ, Ọba Ọjọgbọn Oluṣẹgun Alexander MacGregor lori akitiyan rẹ ninu eto idagbasoke ilu, paapaa lorileede Naijiria.
Boakai lo gbe oṣuba kare naa lasiko to n gba Ọba MacGregor lalejo nile agbara orileede naa to wa niluu Monrovia laipẹ yii.
Nibẹ ni Aarẹ Boakai ti sọ pe oun ko le gbagbe ipa ti Naijiria ko ninu idagbasoke orileede naa, ati iranlọwọ ti awọn alaṣẹ ṣe lati dẹkun ipenija ogun to koju Liberia laarin ọdun 1990 si 2003.
Ọba MacGregor lo lọ pẹlu olori rẹ laafin, Ọmọlara MacGregor ati ikọ akọwọrin ti awọn bii Bọbajiro Ilawọ, Aarẹ Tunde Debayọ-Doherty; Oloye Samuel Erigha Williams, Oloye Ọlayinka Junaid, Ambassador Tosin Ṣanusi, ati awọn miran.
Boakai ni awọn yoo tubọ maa mọ riri orileede Naijiria ni gbogbo igba, nitori pe wọn nawọ ifẹ wọn lasiko iṣoro.
O ṣapejuwe Ọba MacGregor gẹgẹ bii ẹlẹyinju aanu, to n fi tọkantọkan ati awọn ohun to ni sin araalu, paapaa orileede Naijiria, to si lo tun ti gbe ogo ilẹ naa ga lagbaye.
Siwaju sii, lasiko toun naa n sọrọ, igbakeji Aarẹ Liberia, Jeremiah Koung dupẹ gidigidi lọwọ Ọba naa fun ifẹ to fi han si orileede wọn.
Bakan naa la gbọ pe Ọba MacGregor ṣatilẹyin fun ajọ alaanu ti ọmọ Aarẹ Liberia, Tan Tan Boakai, ajọ Yasmin da silẹ fun iranlọwọ araalu.
No comments:
Post a Comment