Ọyawoye di oludamọran pataki lori ọrọ eto ẹkọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 2, 2024

Ọyawoye di oludamọran pataki lori ọrọ eto ẹkọ ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti buwọ lu Ọgbẹni Mohammed Onikọla Ọyawoye gẹgẹ bii oludamọran pataki lori ọrọ eto ẹkọ nipinlẹ Kwara.
 
Ọyawoye to jẹ ọkan lara awọn ọmọ bibi ọjọgbọn ninu imọ Geology, Jamiu Moṣọbalaje ni gomina buwọ lu gẹgẹ bi awọn ipa to ti ko lawujọ eto ẹkọ, pẹlu igbagbọ wi pe yoo lo imọ rẹ fun idagbasoke ati ilọsiwaju.
 
Gomina sọ pe awọn akọsilẹ rere ti ọkunrin naa ni ninu awọon iṣẹ ti wọn ti gbe fun un tẹlẹ lo fa a ti wọn tun fi buwọ lu fun ipo tuntun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI