Ẹgbẹrun mejila apo agbado ati iirẹsi wọ ipinlẹ Kwara, idunnu nla fawọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 11, 2024

Ẹgbẹrun mejila apo agbado ati iirẹsi wọ ipinlẹ Kwara, idunnu nla fawọn araalu


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ti gba baagi agbado ati irẹsi ti ko din ni ẹgbẹrun mejila (12,058).
 
Ninu atẹjade ti Bọla Olukoju to jẹ kọmiṣanna fọrọ eto iroyin nipinlẹ naa buwọ lu, o jẹ ko di mimọ pe lara awọn eto iranwọ tijọba apapọ gbe kalẹ ni.
 
Olukoju ni lara awọn apo ounjẹ ti awọn gba ni baagi agbado ẹgbẹrun meje le diẹ (7,042); apo baagi Millet to din diẹ lẹgbẹrun mẹta (2,916); ati baagi surghum toun le diẹ lẹgbẹrun meji (2,100).
 
Ninu ọrọ rẹ siwaju sii, o jẹ ko di mimọ pe awọn tun gba apo irẹsi kilogiraamu marundinlọgbọn to din diẹ ni ẹgbẹrun mẹsan (8,700).

Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe Minisita fọrọ eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin lorileede yii, Sẹnetọ Abubakar Kyari ni yoo ṣiṣọ loju pinpin awọn ohun elo ounjẹ naa fawọn araalu laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI