Ẹ ṣọra ki wọn ma ba a fi yin ṣetutu aje o - ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun kilọ fawọn ọlọmọge to n ṣiṣẹ aṣẹwo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 2, 2024

Ẹ ṣọra ki wọn ma ba a fi yin ṣetutu aje o - ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun kilọ fawọn ọlọmọge to n ṣiṣẹ aṣẹwo


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn ọṣọrọ ọlọmọgẹ ti wọn fẹran lati maa ṣiṣẹ aṣẹwo lati jawọ, ki wọn ma ba a di ẹni ti wọn fi n ṣetutu aje.
 
O ni awọn ọlọmọge kan wa to jẹ pe lilọ ba awọn ọkunrin fun ibalopọ ni wọn fi n jẹun, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni 'Hook-Up', o ni ki wọn ṣọra daadaa.
 
Ninu ọrọ to kọ soju opo ayelujara ti 'X' rẹ, Ọga ọlọpaa naa ni bi awọn ọlọmọge ti wọn yan iṣẹ 'Hook-Up' laayo ko ba ṣọra wọn, o ṣee ṣe ki wọn fi ori wọn ṣe paṣipaarọ owo.
 
Bẹẹ lo ni kii ṣe gbogbo ohun to n dan ni wura.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI