Aye o! Baale ile yinbọn pa iyawo rẹ to jẹ gbajumọ akọrin ẹmi ninu ṣọọṣi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 13, 2024

Aye o! Baale ile yinbọn pa iyawo rẹ to jẹ gbajumọ akọrin ẹmi ninu ṣọọṣi


Niṣe lọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna laipẹ yii nigba ti wọn sọ pe baale ile kan ti a ko tii mọ orukọ rẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan, ja wọ inu ṣọọṣi lọsan gangan, to si yinbọn pa iyawo rẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni abule Makonde Shadani to wa nitosi Thohoyandou, orileede South Afrika niṣẹlẹ ọhun ti waye lasiko ọdun Easter to kọja lọ yii.

A gbọ pe nnkan bi agogo méfà irọlẹ ni ọkunrin naa ja wọ inu ṣọọṣi lasiko pọpọṣinṣi ọdun, to si yinbọn fun obinrin naa, Arabinrin Funanani Mbedzi.

Wọn ni bo ṣe yinbọn pa iyawo rẹ yii tan lo ti na papa bora ki ọwọ ma ba a tẹ ẹ.

Ninu ọrọ ti ileeṣẹ ọlọpaa to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ, wọn jẹ ko ye wa pe kii ṣsse igba kan ṣoṣo ni ọkunrin naa da ibọn bo iyawo rẹ ko to jade laye.

Colonel Malesela Ledwaba jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ti wọn pe ni Linpopo SAPS ni kayeefi ni iṣẹlẹ ọhun jẹ.

O ni awọn ko tii le ṣalaye idi ti ọrọ fi ri bẹẹ nitori pe iṣẹ iwadii ṣi n lọ lọwọ 

Ledwaba ni ọjọ meji gbako ni ọkunrin naa fi na papa bora, ko to di pe o pada wa fa ara rẹ le awọn ọlọpaa lọwọ.

Ohun lo tun jẹ ko di mímọ pe iwe ẹri ibọn ti ọkunrin naa gba lo jẹ ko l gbe e lati fi pa iyawo rẹ danu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI