Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Ondo ti fi ontẹ luu Gomina Lucky Aiyedatiwa ti ipinlẹ naa, pẹlu awọn mẹẹdogun miran lati kopa ninu eto idibo gomina abẹle to n bọ lọna.
Ogunjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2024 ni eto idibo gomina yoo waye nipinlẹ Ondo, ti awọn ẹgbẹ oṣelu si ti n mura silẹ lati kopa.
A gbọ pe igbimọ ẹlẹni meje to n ṣayẹwo awọn oludije, eyi ti Sẹnetọ Joshua Lidani jẹ alaga lo sọ awọn meje ti yoo kopa ninu eto idibo abẹle to n bọ lọjọ Abamatẹ, ọsẹ yii.
Lara awọn to yege naa Gomina Lucky Aiyedatiwa, Isaac Kekemeke to jẹ igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ APC ni ẹkun Iwọ-Oorun; Olusọji Ẹhinlanwo, toun ti figba kan ri jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin; Olugbenga Edema, ati Sẹnetọ Jimọh Ibrahim.
Awọn miran ni Arabinrin Funmilayo Waheed-Adekojọ, Akinfọlarin Samuel, Adewale Akinterinwa, Oloye Oluṣọla Oke, Ohunyeye Felix ati Morayọ Lebi.
Bẹẹ tun ni Garvey Iyanjan; Ọjọgbọn Francis Faduyile, Arabinrin Judith Ọmọgoroye, Ifẹoluwa Oyedele ati Okunjimi John wa lara awọn ti ajọ naa fi ontẹ lu.
No comments:
Post a Comment