Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii ti jẹ ko di mimọ pe aburo gomina ana nipinlẹ Ondo, Ọjọgbọn Wọle Akeredolu ti gba iṣakoso iyawo ẹgbọn rẹ, Betty-Anyanwu Akeredolu.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn mọlẹbi Betty-Anyanwu ni agbegbe Emeabiam to wa nijọba ibilẹ Owerri West, ipinlẹ Imo.
Lẹyin ọpọlọpọ ajọsọ laarin ẹbi Akeredolu ati Arabinrin Betty Anyanwu ni wọn jọ gba, ti wọn si tọwọ bọ iwe adehun.
Awọn ẹbi Betty-Anyanwu, Umuegeolu ni wọn fa obinrin naa le Ọjọgbọn Wọle Akeredolu lọwọ lati le fidi rẹ mulẹ pe inu awọn dun sii.
No comments:
Post a Comment