AbdulRazaq ba Sẹnetọ Sadiq kẹdun lori iku baba rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 19, 2024

AbdulRazaq ba Sẹnetọ Sadiq kẹdun lori iku baba rẹ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba Sẹnetọ Sadiq Suleiman Umar lati ẹkun Ariwa kẹdun lori iku baba rẹ, oloogbe Alaaji Suleiman Mora Omar.

Alaaji Omar, ẹni to ti figba kan ri jẹ akọwe ileeṣẹ to n ri sọrọ eto irinna lọ si ilẹ mimọ Haj, Kwara State Muslim Pilgrims Board ni wọn lo ku lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun (86years).

Alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii ni baba naa ki aye pe o digboṣe.

Ọdun marundinlogoji ni baba yii lo lẹnu iṣẹ ijọba ko to fẹyinti.

Nigba to n sọrọ, Gomina AbdulRazaq sọ pe ki Sẹnetọ Sadiq ati awọn mọlẹbi maa dupẹ lọwọ Ọlọrun wi pe wọn gbẹyin baba wọn, ati pe oku rẹ kii ṣe akufa.

O ni olufọkansi ni baba, to si fi gbogbo ọjọ aye rẹ sin ipinlẹ Kwara, ati pe orukọ rẹ ko le parẹ nitori awọn ipa rere to ti ko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI