Ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ ni Kwara fẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, o ti ba APC lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 4, 2024

Ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ ni Kwara fẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, o ti ba APC lọ


Gbajugbaja oloṣelu nni, Ọnarebu Aliyu Bahago Ahman-Pategi lati ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ni iroyin ti fi to wa leti bayii pe o ti fẹgbẹ naa silẹ, o si ti ba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lọ nipinlẹ Kwara.
 
Ahman-Patigi lo ṣoju ẹkun Edu/Moro/Patigi, ijọbaibilẹ Ariwa Kwara nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja laarin ọdun 2007 si 2019.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe bi Gomina AbdulRahman ṣe ṣakoso ipinlẹ naa lo fa a ti gbajugbaja agba oloṣelu naa fi pinnu lati ba APC lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI