Alaṣẹ ati oludasilẹ ijo Pentecostal Sanctuary Bible Ministry to wa niluu Ijẹbu-Ode ipinlẹ Ogun ti sọ pe iwa jibiti ati ajẹbanu ko le parẹ lailai.
Wolii Iyunade ni o digba ti ile aye ba dopin, iyẹn ti aye ba parẹ ki iwa ajẹbanu naa too wa si opin.
Olori ijo naa lo sọrọ yii nibi ipade awọn akọroyin to waye ninu ijọ wọn, eyi to wa lara eto ayẹyẹ ọdun mejidinlọgbọn ti wọn da ijọ ọhun silẹ.
Nibẹ lo ti sọ pe ki ẹnikẹni ma lero wi pe ọna abayọ si iwa ajẹbanu ti awọn oloyinbo n pe ni 'Corruption', nitori pe ko le ṣee ṣe.
O ni ohun kan to le ṣẹlẹ ni pe ki adinku wa si iwa ajẹbanu ati jibiti, nipa gbigbe ilana ati ofin kalẹ, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe ko tan patapata.
Wolii naa ni lati ibẹrẹ idasilẹ ile aye ni iwa jibiti ti bẹrẹ, to si ni bi yoo ṣe maa lọ niyẹn titi aye yoo fi parẹ, nitori pe ojoojumọ ni iwa ọmọ araye n buru sii.
"Iwa jibiti ati ajẹbanu ko le dopin. Ohun kan ṣoṣo to le mu ko dopin ni pe ki ile aye pare.
"Bi awọn kan ba n sọ pe onijibiti ni Tinubu, bẹẹ ni wọn ko pa irọ ṣugbọn ko si bi eeyan ṣe le ni iwa buruku to, ti ko nii ni erongba rere fun awọn eeyan."
Nigba to n salaye bi eto ayẹyẹ naa yoo ṣe lọ, o ni ọsẹ kam gbako ni wọn yoo fi ṣe e.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta ni ikede ipolongo ipagọ yoo waye ni agogo mẹta ọsan.
Ọjọ Aje, ojo kejidinlogun si Ọjọbọ, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta ni isọji nla yoo waye ni agogo marun-un ojoojumọ.
Agogo mẹsan aarọ, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlogun si Ọjọbọ, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta ni ipahọ awọn iranṣẹ Ọlọrun ati awọn oṣiṣẹ yoo waye.
Ọjọ Ẹti to tẹle ni aṣalẹ orin iyin yoo waye ni deede agogo mẹwaa alẹ.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹta ni isin idupẹ ati fifi ami ororo yan awọn eeyan yoo waye ninu ijọ ni deede agogo mẹwaa owurọ.
Siwaju sii ni Wolii Iyunade sọ pe gbogbo eto ti yoo waye laarin ọjọ kejidinlogun si ọjọ kọkanlelogun ni yoo waye ninu ijọ naa to wa ni ojule kẹsan, adugbo Ararọmi, Odo-Ẹgbọ, Ijẹbu-Ode.
Nigba ti awọn isin yooku yoo waye ni ilẹ ipagọ wọn to wa ni PSMB Campground, Zion Cotytto wa lopopona Erunwọn/Atan, Ijẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment