Gbajugbaja onkọrin Fuji nni, Wasiu Ayinde Marshal ti ọpọ mọ si K1 De Ultimate ti sọ pe ko si nnkan gidi to n ṣẹlẹ ni Naijiria lasiko yii, to le mu koun ṣayẹyẹ ọjọ ibi oun to n bọ.
Wasiu Ayinde lo sọrọ yii loju opo Instagram rẹ laipẹ yii, to si ni ki awọn to ba fẹẹ wa ba oun ṣayẹyẹ ọjọ ibi oun jokoo sile wọn
Bakan naa lo tun sọ pe ki gbogbo awọn to n palẹmọ lati fi owo ranṣẹ soun daa duro, ki wọn si fi awọn owo ọhun ta awọn alaini to wa lagbegbe wọn lọrẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o ni “ko si nnkan gidi to n ṣẹlẹ lorileede Najiiria lasiko yii to le mu ki eeyan ronu lati ṣayẹyẹ ọjọ-ibi ni saa ti a wa yii.
“ẹyin ololufẹ mi, kaka ki ẹ wa lati ba mi ṣajọyọ, ti ẹ maa jẹ, ti ẹ fi maa mu lasiko yii, ẹ dakun, anfaani ayẹyẹ yii lasti fi ran awọn eeyan to wa nitosi yin lọwọ.”
No comments:
Post a Comment