Alaṣẹ ati olidasilẹ ijọ Pentecostal Sanctuary Bible Ministry to wa niluu Ijẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun, Wolii Sunday Dare Iyunade ti sọ ọ jade sita wi pe ki awọn ọmọ orileede Naijiria lọ fọkan balẹ, nitori pe ayipada rere ṣi n bọ labẹ iṣakoso yii.
Wolii Sunday Iyunade sọ pe ireti nla lo wa wi pe nnkan yoo pada bọ sipo gẹgẹ bi afojusun awọn araalu.
Gbajugbaja Wolii naa lo sọrọ yii lonii Ọjọ Aje, Mọnde ninu ijọ naa to wa niluu Ijẹbu-Ode nibi ipade awọn akọroyin to waye, eyi to wa lara eto ayẹyẹ ọdun mejidinlọgbọn ti wọn da ijọ ọhun silẹ.
Nibẹ lo ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria nilo ọpọlọpọ suuru, nitori atunto nla yoo ṣẹlẹ, eyi ti yoo mu ki ireti araalu wa si imuṣẹ.
Bakan naa lo tun sọ pe iditẹ nla yoo ṣẹlẹ, ṣugbọn nitori ti Ọlọrun ko lọwọ sii, ijakulẹ ni iditẹ ọhun yoo ja si.
Ninu asọtẹlẹ ti Wolii Iyunade fi sita, o ni:
"Awọn ọmọ Naijiria nilo ọpọlọpọ suuru. Ijọba yoo ṣe atunto ti yoo fi ẹsẹ mulẹ, ati pe inu iṣakoso yii naa ni atunto ọhun yoo ti bẹrẹ, ti iṣakoso to n bọ lẹyin rẹ yoo si tẹle.
"Naijiria yoo jẹ aarin gbungbun gbogbo ipinnu agbaye. Bi awọn eeyan yoo ṣe maa wọ Naijiria lati gbe wa lara ipinnu Ọlọrun. Asọtẹlẹ yii ti wa nilẹ tipẹ.
"Ireti ṣi wa fun wa gẹgẹ bi ọmọ Naijiria; a maa kuro ninu ninu ilakaka eto ọrọ aje to dorikodo. Ọlọrun ti fi da wa loju pe ṣisẹ-n-tẹle ni ayipada ọhun yoo jẹ. Omo Naijiria yoo gba agbara rẹ pada.
"A ni lati maa gbadura fun Aarẹ orileede yii, ki o le jẹ ki awọn ileri ati erongba rẹ ni kọọrọ ko to de ijọba wa si imuṣẹ.
"Iṣakoso yii kan n palẹmọ fun ijọba to n bọ ni, ẹlomiran lo maa pari rẹ.
"Mo ri Ọlọrun ẹsan to n dide lori ọrọ Naijiria. Ajalu nla ṣi n bọ lori awọn to n da Naijiria laamu, ati gbogbo awọn to n ko idaamu ba Naijiria.
"Iditẹ yoo ṣẹlẹ ni Naijiria. Eyi yoo si jẹ nla. Wọn ti n gbe e dide bayii. Wọn maa gbiyanju rẹ, ṣugbọn nitori Ọlọrun ko lọwọ sii, yoo ba ijakulẹ pade ati pe ko si iye ifẹhonuhan lati pin Naijiria ti yoo ṣee ṣe.
"Ko si ni ipinnu Ọlọrun lati pin Naijiria. Ki awọn adari wa gba awọn ileeṣẹ ti wọn jẹ ti ọmọ orileede yii laaye, dipo ki awọn ara ita maa wa da ileeṣẹ silẹ."
No comments:
Post a Comment