Ọrọ kan ti awọn Yoruba maa fi n da aṣa pe 'Ko si bi a ti se ebolo ti ko nii run igbẹ', ati pe 'Aja ti yoo sọnu, ko ni gbọ ffere ọlọdẹ' lo lọ ni ibamu pẹlu bi ọwọ ṣe tẹ baba arugbo yii.
Dauda Lamidi lorukọ baba arugbo, ẹni ọdun marundinlaadọrin (65years) naa ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju igbo tita lọ.
A gbọ pe Dauda Lamidi ṣẹṣẹ de lati ọgba ẹwọn ni, ṣugbọn kaka ko tọwọ rẹ bọ aṣọ, ko si jawọ ninu iwa ọdaran, niṣe lo tun gbe igba igbo.
Gẹgẹ bi ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun lorileede Naijiria, National Drug Law and Enforcement Agency, NDLEA, ẹka tipinlẹ Ọṣun ṣe sọ, wọn ni ibi ti Lamidi ti n ta igbo lọwọ ti tẹ ẹ.
Ninu ọrọ Odigie Charles to jẹ agbẹnusọ ajọ naa niluu Oṣogbo, lasiko to n foju Lamidi han fawọn akọroyin, o ni ọjọ Satide, ọsẹ to kọja yii lọwọ tẹ ẹ.
Inu galọọnu oili (oil) ni wọn sọ pe o n ko igbo naa si, ki aṣiri ma ba a tu sita, ṣugbọn to ni omi pada dilẹ lẹyin asunṣujẹ rẹ.
Ọdun 2019 ni wọn ju Lamidi sẹwọn ọdun mẹta pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun kan naa, ṣugbọn ti wọn sọ pe aja rẹ tun pada sidi eebi rẹ lẹyin to jade sita.
No comments:
Post a Comment