Awọn ajinigbe ha ni Kwara, ọkan ku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 5, 2024

Awọn ajinigbe ha ni Kwara, ọkan ku


Agbarijọ awọn ileeṣẹ eleto aabo ti rọwọ to awọn afurasi ajinigbe kan ti a gbọ pe wọn n gbero lati ji awọn eeyan gbe nipinlẹ Kwara.
 
Awọn ti ko din ni marun-un lọwọ tẹ, nigba ti ọkan ninu wọn fara gbọta, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, abule Alọ to wa nijọba ibilẹ Ifẹlodun la gbọ pe aṣiri naa ti tu si awọn ọlọpaa ati ikọ fijilante ti wọn pawọpọ lati gbogun ti awọn ajinigbe lọwọ.
 
Wọn ni abule Alọ yii gan-an ni wọn fi ṣe buba, nibi ti wọn n ko awọn ti wọn ba jigbe pamọ si lati gba owo.
 
Awọn meji la gbọ pe wọn farapa yannayanna ninu awọn ajinigbe meji naa, pẹlu ọgbẹ ọta ibọn.
 
Saidu Soliu ati Soliu Abass lorukọ awọn mejeeji.
 
Ibrahim Muazu, ọmọ ọgbọn ọdun; Asimu Salisu ati Aminu Alaka ti wọn jẹ ẹni ọdun marundinlọgbọn; Aminu Temino ati Zakariyau Suleiman ti wọn jẹ ọmọ ogun ọdun lorukọ awọn marun naa.
 
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni ibọn agbelẹrọ meji; Ibọn nla Ak47 mejila to jẹ 7.62mm; Ibọn nla (Expended) AK47 to jẹ 7.62mm.
 
Ibọn kan ti ko ni ọta ninu, ada kan ati awọn ohun ija oloro miran.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Victor Olaiya ti ṣalaye pe iṣẹ iwadii awọn ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI