Aisan iba Lassa tun pa ogun eeyan nipinlẹ mẹrindinlogun laarin ọsẹ kan - NCDC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 21, 2024

Aisan iba Lassa tun pa ogun eeyan nipinlẹ mẹrindinlogun laarin ọsẹ kan - NCDC


Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorileede Naijiria, Nigeria Centre for Disease Control and Prevention, NCDC, ti kede sita pe ko din ni ogun eeyan ti aisan iba Lassa ti pa danu.
 
NCDC sọ pe aarin ọsẹ kan pere ni aisan Iba Lassa naa pa awọn eeyan wọnyi nipinlẹ mẹrindinlogun to wa lorileede yii.
 
Wọn ni laarin ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji si ọjọ kẹta, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii ni awọn eeyan naa ku.
 
Nigba ti wọn n fidi rẹ mulẹ loju opo ayelujara wọn, wọn jẹ ko di mimọ pe ni ọsẹ kẹsan ninu ọdun 2024, awọn ti ṣe akọsilẹ aisan naa to tun ga ju ti tẹlẹ lọ.
 
Aisan iba Lassa le debi pe o n gba ẹmi loju ẹsẹ, eeyan si le ko aisan yii loriṣiriṣi ọna.
 
Lara awọn apẹẹrẹ aisan yii ni iba, ọgbẹ ikọfun, rirẹ ara, ikọ ife, eebi, egungun riro, aya didun, ẹjẹ dida lati oju, imu ati ẹnu ati bẹẹ lọ.
 
Ajọ naa ti wa jẹ ko di mimọ pe igbesẹ ti n lọ lọtun-losi lati rii pe wọn dẹkun itankalẹ aisan naa, nitori pe awọn ti ṣe akọsilẹ mọkandinlaadọfa (109) laarin ọsẹ kan pere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI