Awọn agba ninu ẹgbẹ ṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Kwara ni iroyin ti fi to wa leti wi pe wọn ti fẹgbẹ silẹ, ti wọn si ti ba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lọ.
Ọnarebu Abubakar Suka Baba to jẹ alẹnulọrọ lẹgbẹ PDP ni ijọba ibilẹ Ariwa Kwara ati Abubakar Musa ti ọpọ mọ si Biology ni wọn ti fẹgbẹ naa silẹ bayii.
Iyẹn nikan kọ, wọn lawọn mejeeji yii tun ko gbogbo awọn ọmọ ẹyin ati awọn alatilẹyein wọn kuro lẹgbẹ PDP lọ si APC.
Baba ni igbakeji olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa tẹlẹri, to si tun ti figba kan ri jẹ alaga ẹgbẹ awọn olukọ ti Nigeria Union of Teachers, bakan naa lo tun ti figba kan ri gbe apoti gẹgẹ bi aṣojuṣofin ninu eto idibo ọdun 2019, bo tilẹ jẹ pe ko wọle.
Nibi ayẹyẹ nla to gbe kalẹ nijọba ibilẹ Kaiama nibi to ti kede sita faraye wi pe oun ti ba ẹgbẹ APC lọ, Baba ni oun ko le tẹsiwaju lati maa wa ninu ẹgbẹ ti ko ni afojusun rere naa mọ.
Baba ati Musa nigba ti awọn mejeeji n sọrọ lọtọọtọ jẹ ko di mimọ fawọn alatilẹyin wọn wi pe awọn iṣẹ iwuri manigbagbe ti gomina Kwara n ṣe lo wu wọn lori, ti wọn fi pinnu lati darapọ mọ ọn.
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọọba Sunday Fagbemi nigba to n gba ẹnu awọn oloye ẹgbẹ APC sọrọ sọ pe idunnu nla lo jẹ lati gba wọn wọle sẹgbẹ.
O ni iṣakoso AbdulRazaq lati ọdun 2019 ti mu ileri rẹ ṣẹ, to si ti fun awọn araalu, paapaa awọn ara agbegbe Ariwa Kwara ni ireti ọjọ iwaju rer.
Bakan naa, alaga ẹgbẹ Alliance for Sustainable Kwara (ASK), Malam Razaq Lawal ati awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn fi idunnu wọn han wi pe ipinlẹ Kwara n tẹsiwaju.
No comments:
Post a Comment