Lojuna lati din ebi, iṣẹ ati oṣi ku laarin ilu, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq ti bẹrẹ pinpin ounjẹ, papaaa irẹsi fun awọn araalu.
Ijọba Kwara pin baagi irẹsi kilogiraamu mẹwaa (10Kg) nipasẹ awọn ajọ araalu bii Community–Based Organizations (CBOs), Non-governmental Organizations (NGOs), Civil Society Organizations (CSOs) kaakiri ipinlẹ ọhun.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọfiisi amugbalẹgbẹ agba pataki lori ọrọ idagbasoke agbegbe, Ọmọwe Lawal Ọlọhungbẹbẹ ni iroyin fi to wa leti o n ṣagbatẹru pinpin irẹsi iranwọ naa sita lai ṣe ojusaaju.
Ẹgbẹrun lọna ogun ni ipele irẹsi ti a gbọ pe wọn n pin bayii.
Nipasẹ ẹgbẹ Ṣaa-Ṣaa-Ṣaato n ṣabojuto awọn agbegbe ati igberiko, awọn olori ẹsin ati awọn agbaagba, to fi mọ awọn alẹnulọrọ laarin ilu ni ijọba fi n pin awọn irẹsi ọhun, ko le kari gbogbo eeyan nijọba ibilẹ mẹrindinlogun to so ipinlẹ Kwara papọ.
Ṣaaju asiko yii, ẹgbẹ oṣiṣẹ Nigerian Labour Congress ati Trade Union Congress (TUC) ni wọn ti kọkọ jẹ anfaani baagi irẹsi ẹgbẹrun mẹwaa ti wọn pin f'awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.
No comments:
Post a Comment