O ma ṣe o...wọn gun Ifẹoluwa, akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin pa l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 5, 2024

O ma ṣe o...wọn gun Ifẹoluwa, akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin pa l'Ondo


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iku akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin to wa ni Akungba Akoko, ipinlẹ Ondo ṣi n jẹ, lori bi wọn ṣe gun un pa.
 
Inu yara ni wọn pa akẹkọbinrin naa, Ifẹoluwa Adekunle to wa ni ipele kẹta, ẹka ikẹkọọ Economics lopin ọsẹ to kọja yii.
 
Lara awọon ara adugbo to sọrọ ṣalaye pe ko tii sẹni to le sọ pato ẹni to ba Ifẹoluwa sinu yara rẹ.
 
Wọn ni ẹnikan lo wa kii nile lọjọ naa, ṣugbọn to pada jẹ pe oku rẹ ni wọn ba lẹyin ti ẹni naa jade.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Funmilayọ Ọdunlami sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ awọn to pa Ifẹoluwa.
 
Ọdunlami ni awọn ti gbe oku Ifẹoluwa lọ si mọṣuari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI