Ọga agba pata fun ileeṣẹ ologun lorileede Naijiria, Ọgagun Taoreed Lagbaja ti sọ pe atilẹyin ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq n ṣe fun ikọ ẹgbẹ ologun n'ipinlẹ naa lo mu ki alaafia maa jọba.
Lagbaja lo sọrọ naa lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee lasiko abẹwo ibanikẹdun ti gomina ṣe lọ si olu-ileeṣẹ ologun pẹlu awọn alẹnulọrọ ninu ijọba.
Nibẹ lo ti ṣalaye pe kani kii ṣe atilẹyin ati iranlọwọ ti gomina n ṣe fun ileeṣẹ ologun, o ṣee ṣe ki ọrọ eto aabo ti mẹhẹ.
Bakan naa lo gbe oṣuba kare fun gomina yii lori atilẹyin to tun ṣe fun mọlẹbi oloogbe Ṣẹgun Oni, ọmọ ologin to padanu ẹmi rẹ soju ogun lọdun to kọja.
Ọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ, ọdun 2023 ni Ṣẹgun Oni pade iku ojiji loju ogun, lasiko ti wọn lọ koju awọn agbebọn aṣekupani n'ipinlẹ Niger.
Nigba toun naa n sọrọ, AbdulRazaq dupẹ lọwọ iranlọwọ eto aabo ti ileeṣẹ ologun n ṣe n'ipinlẹ Kwara, to si lawọn ohun to n mu ori oun wu niyẹn.
O ni loore koore loun yoo ma ṣatilẹyin fun ikọ ologun, paapaa awọn eleto aabo.
No comments:
Post a Comment