Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele, l’Ọjọbọ, Tọside ti parọwa si Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu lati ma ṣe gbọ ọrọ ẹtan ti igbakeji rẹ, Kashim Shettima ati Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Godswill Akpabio sọ pe ko si iṣoro kankan to n koju awọn ọmọ Naijiria lasiko.
Wolii Ayọdele sọ pe iwọde ifẹhonuhan ti awón araalu n ṣe lasiko, awọn kan lo n ṣagbatẹru ẹ.
O ni ọrọ ẹtanjẹ lasan ni Shettima ati Akapbio n sọ fun Tinubu nitori pe lotitọ ni awọn ọmọ Naijiria n koju iṣoro, eyi lo si mu ki wọn pinnu lati bọ sigboro lati fẹhonu wọn han.
Wolii Ayọdele lo sọrọ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Oluwatosin Ọṣhọ gbe jade laarọ oni, Tọside.
Nibẹ lo ti ni Shettima ati Akpabio n fi ibinu awọn araalu ta tẹtẹ, ti wọn si fi n ṣe ọrọ oṣelu dipo ki ijọba wa ọna abayọ si iṣoro ti araalu n koju.
“Orileede yii nilo idasi pajawiri, bi bẹẹ kọ, awọn ọmọ Naijiria yoo tubọ maa koju iṣoro nla ni. Tinubu ko gbọdọ da awọn to n tan an jẹ lohun, nitori awọn eeyan wa ninu irora, ko si sẹni kankan to n ṣagbatẹru iwọde ifẹhonuhan.
“Awọn eeyan n binu, wọn si n la ooru ina eto ọrọ aje kọja. Tinubu ko gbọdọ gbọ ọrọ ẹtanjẹ ti ko nii tan iṣoro to n koju awọn eeyan lasiko yii, gbogbo nnkan lo ti dorikodo.
“Tinubu ni lati gbe igbesẹ ko too pẹ ju. Ọrọ ti Akpabio sọ nipa iwọde kii ṣe ọrọ ọlọgbọn rara, o gbẹgẹ gidi. Bi Shettima ati Akpabio ṣe n sọ pe awọn kan lo n ṣagbatẹru iwọde ko ba iwa ọmọluabi mu.
“Ko sẹni to n ṣagbatẹru ohunkohun, ebi n pa awọn eeyan, ati poe awọn ohun ti Ọlọrun ti sọ pe yoo ṣẹlẹ ninu iṣẹjọba rẹ lo n ṣẹlẹ lasiko yii.
“Awọn araalu ko nilo ọrọ buruku lasiko yii. Dipo ki ẹ maa tabuku ba awọn kan, ijọba rẹ gbọdọ bẹrẹ iṣẹ atunṣe.”
No comments:
Post a Comment