Iyawo gomina ipinlẹ Kwara, Arabinrin Olufọlakẹ Abdulrazaq ti fi idunnu rẹ han lori bi ileeṣẹ iwe iroyin The SUN ṣe fi ẹbun aami ẹyẹ daa lọla gẹgẹ bi ipa to n ko lawujọ awọn obinrin nipinlẹ naa, ati lorileede Naijiria.
Olufọlakẹ AbdulRazaq ni iyawo gomina to peregede julọ lọdun 202, gẹgẹ bi awọọdu idalọla naa ṣe sọ.
Nigba to n fi idunnu rẹ han, Aṣiwaju awọn obinrin nipinlẹ Kwara naa sọ pe iwuri ati idunnu nla lo jẹ foun wi pe awọn kan mọ riri ipa toun n ko lawujọ.
O ni bo tilẹ jẹ pe oun yoo fi awọọdu ọhun jin fun Ọlọrun ọba, sibẹ o tun loun yoo fi jin awọn araalu ti wọn gbe iṣẹ oun yọ, nitori pe awọon gan an ni alatilẹyin oun.
Bakan naa lo ṣeleri pe awọọdu yii tun ti è oun nija lati ṣe ju boun ṣe n ṣe tẹlẹ lawujọ lọ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn iyawo gomina lorileede Naijiria
Bẹẹ lo tun ki gbogbo awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ gba aami ẹyẹ idalọla naa.
No comments:
Post a Comment