Idagbasoke agbegbe: Ijọba Kwara gbe eto idanilẹkọọ kalẹ fawọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 7, 2024

Idagbasoke agbegbe: Ijọba Kwara gbe eto idanilẹkọọ kalẹ fawọn araalu


Lojuna lati le jẹ ki araalu mọ bi wọn ṣe le mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba awọn agbegbe ati ayika wọn, ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe akanṣe eto idanilẹkọọ kalẹ fawọn araalu.

Ileeṣẹ amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina lori ọrọ eto idagbasoke agbegbe (Senior Special Assistant on Community Development (OSSACD)) lo gbe idanilẹkọọ ọhun kalẹ.

Lasiko to n sọrọ nipa koko pataki idi to fi gbe eto ọhun kalẹ, Ọmọwe Lawal Ọlọhungbẹbẹ sọ pe lati mu ajọṣepọ to dan mọnran wa laarin ileeṣẹ oun ati awọn agbegbe to fi mọ igberiko.

O ni eyi yoo jẹ ki onikaluku mọ ọna ti wọn le gba lati jẹ ki ilọsiwaju ba agbegbe wọn.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI