Gómìnà AbdulRazaq fún akẹ́kọ̀ọ́ Kwara mẹ́fà tó tayọ níbi ìdíje l'Abuja ní ìwé sọ̀wédowó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 2, 2024

Gómìnà AbdulRazaq fún akẹ́kọ̀ọ́ Kwara mẹ́fà tó tayọ níbi ìdíje l'Abuja ní ìwé sọ̀wédowó


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi iwe sọwedowo ta akẹkọọ mẹfa ti wọn gbe ipo kinni ninu idije to waye niluu Abuja.

Lara awọn ileri ti Gomina ṣe lo ti mu wa si imuṣẹ yii.

Awọn mẹfa naa ni Mashood Kamaldeen (Government Secondary School, Ilorin East LG); Jatto Ramatallahi (Offa Grammar School, Offa); Jimoh Abayomi Emmanuel (Tanke Community Junior Secondary School, Ilorin South); Emmanuel Chioma (St. Anthony Junior Secondary School, Ilorin East); Dolapo Mariam (Offa Grammar School, Offa); ati AbdulKareem Uswat (Okelele Junior Secondary School Ilorin East).

Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti ki wọn ku oriire aṣeyọri nla naa, to si tun ba awọn obi awọn ọmọ ọhun dupẹ fun oriire nla to wọle tọ wọn.

Gomina ṣeleri pe ijọba oun yoo rii daju pe gbogbo bi eto ẹkọ awọn ọmọ naa ba ṣe n lọ loun yoo maa mojuto, lati rii pe wọn ṣe aṣeyọri nla lọjọ iwaju wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI