Gbogbo awọn to lọwọ ninu iku Ọba Arẹmu lọwọ yoo tẹ laipẹ - Gomina AbdulRazaq ṣeleri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 2, 2024

Gbogbo awọn to lọwọ ninu iku Ọba Arẹmu lọwọ yoo tẹ laipẹ - Gomina AbdulRazaq ṣeleri


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu si Aafin Olukoro tilu Ikoro nijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara, nibi ti wọn ti pa kabiyesi, Ọba ajagunfẹyinti Ṣẹgun Arẹmu.

Yatọ si pe wọn pa Ọba Arẹmu, wọn tun ji iyawo rẹ ati awọn meji miran wọnu igbo lọ, iyẹn l’Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ yii.

Nigba to n sọrọ lori ikọlu naa, Gomina AbdulRazaq sọ pe ajalu nla ni ikọlu ọhun jẹ, to si jẹ eewọ nla si ipo ori ade.

Gomina rọ awọn eleto aabo lati rọwọ to gbogbo awọn to mọ nipa ikọlu si Aafin Olukoro naa lati fi wọn j’ofin.

Bakan naa lo ba idile Kabiyesi ati gbogbo araalu kẹdun iku ati ikọlu naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI