Agbaboọlu Mexico, Diego Chavez ku sinu ijamba ọkọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 15, 2024

Agbaboọlu Mexico, Diego Chavez ku sinu ijamba ọkọ


Ọkan lara awọn agbọọlu ọmọ orileede Mexico nni, Diego Chavez ni iroyin ti fi to wa leti bayii pe o ti ku.
 
Chavez, ọmọ ọdun mejidinlọgbọn nni to n gba bọọlu fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu FC Juarez la gbọ pe o dagbere faye ninu ijamba ọkọ rẹ.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni ọkọ onijapa Volkswagen Beetle rẹ lo da iṣẹ silẹ lori ere, to si ṣe bẹẹ lọ kọlu opo kan.
 
Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ ti wa fi ẹdun ọkan wọn han si ijamba naa, ti wọn si ti b ara wọn kẹdun iku oloogbe naa l'Ọjọru, Wẹside tọ kọja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI