Igbakeji Aarẹ orileede Naijiria, Kashim Shettima ti pada si orileede Ivory-Coast lati wo bi aṣekagba idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ to n lọ lọwọ yoo ṣe pari.
Ẹgbẹ agbabọọ lu Super Eagles ni yoo maa waako pẹlu akẹgbẹ, Ivory Coast ti wọn ṣagbatẹru idijẹ ọhun lọjọ Aiku, Sannde, ọla.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Shettima naa wa ni papa iṣere Stade de la Paix to wa ni Bouake l’Ọjọru, Wẹside, ọsẹ nibi ti ikọ Super Eagles ti koju Bafana-Bafana ti orileede South Afrika.
Papa iṣere Alassane Ouattara to wa niluu Abidjan, olu ilu Ivory Coast to tun n jẹ Cote D’Ivoire ni ifigagbaga ọhun yoo ti waye ni deedee agogo mẹsan alẹ.
Nibi ipade awọn akọroyin, Aarẹ ajọ to n ṣagbatẹru ere idaraya ni Naijiria, CAF, Patrice Motsepe, nigba to n sọrọ lọjọ Ẹti, Fraide ana jẹ ko di mimọ pe Aarẹ Bọla Tinubu funra rẹ yoo wa ni Ivory Coast lati wo ifẹsẹwọnsẹ to gbẹyin.
Ṣugbọn ni bayii, Aarẹ Tinubu ko ni le lọ lati wo ifigagbaga ọhun, idi re to fi yan igbakeji lati lọ ṣoju rẹ.
No comments:
Post a Comment