Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ ti idile Oloogbe Alaaja Dupẹ Belgore to jẹ iyawo Jarma tiluu Ilọrin, Alaaji Kọla Belgore.
AbdulRazaq nigba to n ṣapejuwe oloogbe naa, o ni lara awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn fi ara wọn jin fun iṣẹ ilu ni Alaaja Belgore jẹ nigba to wa lẹnu iṣẹ.
O ni ọkan pataki lara awọn igi lẹyin ọgba fun mọlẹbi ati olori agbegbe ti kii fi igba kan bo ọkan ninu ni.
Bo ṣe n gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere, naa lo tun gbadura pe ki Ẹlẹdaa mu awọn mọlẹbi rẹ lọkan le lasiko ipadanu nla yii.
No comments:
Post a Comment