AbdulRazaq buwọ lu igbimọ ti yoo tọpinpin bi idagbasoke yoo ṣe ba ile-ẹkọ olukọni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 22, 2024

AbdulRazaq buwọ lu igbimọ ti yoo tọpinpin bi idagbasoke yoo ṣe ba ile-ẹkọ olukọni


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti buwọ lu igbimọ amuṣẹṣe ati amuṣẹya ti yoo tọpinpin bi idagbasoke ati ilọsiwaju yoo ṣe ba awọn ile-ẹkọ olukọni to wa niluu Oro, Ilọrin ati Lafiagi.
 
Awọn ti gomina buwó lu yii ni yoo ṣe iwadii lati mọ iru awọn eto ati ilana ẹkọ ti wọn yoo fi kun ilana eto ẹkọ wọn lati le jẹ si itẹsiwaju ba awọn ile-ẹkọ naa gẹgẹ bi erongba ijọba.
 
Inu oṣu kẹwaa ọdun 2023 ni Gonina AbdulRazaq ti kọkọ kede igbimọ naa si awọn ile-ẹkọ ọhun, Colleges of Education ti Oro, Ilọrin, ati Lafiagi.
 
Awọn igbimọ naa lẹyin abẹwo ti wọn ṣe ninu oṣu kini, ọdun 2024 fi esi abajade wọn to ijọba leti.
 
Lara awọn igbimọ ọhun ni;

A. College of Education, Ilorin

1: Prof. Jimada Idris Shaaba (Alaga)
2: Hajia Afusat AbdulRahman 
3: Hajia Eletu Halimat Aduke 
4: Dr. Seyi Oloyede 
5: Hon. Dele Abiodun 
6: Hajia Bilikis Olatundun Suleiman 
7: Dr. Ayoku Oba Babatunde 
8: Peter Ghana Abu (Akọwe)

B: College of Education, Oro

1: Prof. Mrs. Binta Jibola Sulyman (Alaga)
2: Barrister Bature Ismail 
3: Architect Thomas Gana 
4: Barrister Temim Aisha 
5: Mrs. Bola Olaoye 
6: Architect Shakirudeen Oladotun 
7: Hon. Omo Abass Taofik 
8: AbdulGaniy Shuaib (Akọwe)
 
C: College of Education (Technical) Lafiagi 

1: Dr. Fatai Bello (Alaga)
2: Mrs. Fakayode Folushe 
3: Barrister Yahaya Ndakene 
4: Dr. Safi Lawal 
5: Engineer Usman Bayero 
6: Rebecca Yaga 
7: Barrister Muslima Nagode 
8: Mr. Salami Adeshina (Akọwe).

Ọsẹ meji pere ni awọn igbimọ wọnyi ni lati fi esi abajade wọn to ijọba leti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI