A ni lati fi gbgobo okun ati agbara wa gbadura, ki ayipada rere le de ba owo naira - Baba Adeboye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 5, 2024

A ni lati fi gbgobo okun ati agbara wa gbadura, ki ayipada rere le de ba owo naira - Baba Adeboye


Alakoso ati olori ijọ The Redeemed Christian Church of God kaakiri agbaye, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti kọminu lori bi owo naira ṣe n jẹ awọn ọmọ Naijiria niya lasiko yii.

Pasitọ Adeboye ni asiko ti to fun awọn ọmọ Naijiria lati dide gbadura kikan, ati pe ki wọn lo okun ati agbara ti wọn ni lati fi gbadura ti yoo mu ayipada rere ba owo naira.
 
Baba Adeboye ni ọpọ araalu ni iya n jẹ lasiko yii, to si kọja afẹnuroyin.
 
Lasiko to n sọrọ nibi isin idupẹ oṣu keji ti wọn pe akori rẹ ni Jẹ Ki Afẹfẹ Fẹ - ‘Let The Wind Blow’, to waye ni olu-iya ijọ naa ti Throne of Grace Parish, Ebute Mẹta, ipinlẹ EKoo lọjọ Aiku, Sannde ana, o ni adura ṣe pataki pupọ.
 
Ẹ ma gbagbe pe ni ibẹrẹ ọdun yii, Ọlọrun sọ pe nnkan yoo buru ko to di pe o dẹrun pada. Bi ẹ ba mọ iye ti owo naira si dọla jẹ ni ọjọ kinni, oṣu kinni, ki ẹ wa lọ ṣagbeyẹwo rẹ si iye to wa bayii, niṣe lo maa dani ẹni pe ọmọ yii mọ ohun to n sọ.
 
“A ni lati fi okun ati agbara wa gbadura nitori pe nigba ti a ba sọ pe nnkan maa le koko ko to pada dẹrun. A ko mọ bo ṣe maa buru si, bẹẹ si ni a ko le sọ igba ti nnkan yoo dẹrun.
 
“Pẹlu gbogbo ọkan rẹ, ẹ sunkun si Ọlọrun lọrun, ko si le foju aanu wo wa, ki Ọlọrun tete gbakoso.
 
“Ko nii ṣe pẹlu iye ti wọn n ṣẹ owo dọla, aabo wa fun. Gomina ko nilo lati mọ iye ti wọn n ra epo rọbii; ko si fẹẹ mọ iye epo to wa ninu mọto ẹ.

“Nigba to ba fẹẹ jade, yoo kan bọ sita wọ inu mọto rẹ ni. Kii lọ to lati ra epo.
 
“Aarẹ ko nilo lati mọ iye ti wọn n ta burẹẹdi; iyẹn ko kan an rara; burẹẹdi gbọdọ de ori tabili rẹ nigba to ba fẹẹ jẹ ẹ.
 
“Emi ati ẹyin nikan naa la le mọ iye ti wọn n ta irẹsi lati bẹrẹ ọdun yii nitori pe a ni lati ra a.
 
“Mo ti sọ fun un yin pe mi o kii ṣe Wolii, Ojiṣẹ Ọlọrun ni mi. Ni ibẹrẹ ọdun yii, Ọlọrun sọ pe afẹfẹ yoo fẹ. Bo ṣe wa bayii, ko si ohun ti a le ṣe lati daa duro.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI