Wọn fẹsun kan Elon Musk wi pe o n mu egboogi oloro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 8, 2024

Wọn fẹsun kan Elon Musk wi pe o n mu egboogi oloro


Wọn ti fi ẹsun egboogi oloro kan Elon Musk, alaṣẹ ileeṣẹ ikanni ayelujara ti a mọ si X, Tiwtter tẹlẹ, ti wọn si ni inu ileeṣẹ rẹ lo ti n mu egboogi oloro.

Ninu ohun ti a gbọ, wọn sọ pe awọn egboogi oloro Elon Musk n mu yii, lo n fa awọn iwa janduku to n hu lọpọ igba.
 
Iwa rẹ ni wọn si lo n kọ awọn alakoso ileṣẹ rẹ lominu.
 
Wọn ni o ṣee ṣe ki egboogi oloro yii ṣakoba fun ilera gbajugbaja ati ogbontarigi onimọ igbalode naa, ati pe o tun le ni ipalara ninu awọn ileeṣẹ rẹ bii Tesla ati SpaceX.
 
Ẹ ka ẹkunrẹrẹ siwaju nibi : Musk n mu egboogi oloro

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI