Ọwọ ti tẹ Abubakar to gun iyawo rẹ pa loju orun - Ọlọpaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 5, 2024

Ọwọ ti tẹ Abubakar to gun iyawo rẹ pa loju orun - Ọlọpaa


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Yobe to wa niluu Damaturu ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ baale ile, ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Abubakar Musa lori ẹsun wi pe o gun iyawo rẹ, Ammi Adamu Mamman pa lati oju orun.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Dungus Abdulkarim fi ọrọ ọhun lede ninu atẹjade to gbe sita laipẹ yii.

Ninu atẹjade ọhun,
Abdulkarim sọ pe ni nnkan bi aago marun ku iṣẹju mejidinlogun aarọ kutu ọjọ kẹrin, oṣu kinni, ọdun 2024 ni awón gba ipe wi pe ẹnikan to njẹ Abubakar Musa gun iyawo rẹ pa.

O ni adugbo ti wọn n pe ni New Housing Estate, Bye-pass, Maiduguri Road, Damaturu, ni ọkunrin naa n gbe pẹlu iyawo rẹ. Nibẹ lo si ti fi nnkan gun un lọrun pa, ẹyi to jẹ ki ẹjẹ da rẹpẹtẹ lara obinrin naa.

Abdulkarim tẹsiwaju pe awọn mu ọkọ obinrin naa lati fi ọrọ wa a lẹnu wo, nipa ohun to ṣokunfa iku iyawo rẹ.
 
Iwadii fi han pe oṣiṣẹ fasiti ipinlẹ Yobe to wa niluu Damaturu ni ọkọ ati iyawo naa.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI