Ọdun aṣeyọri to pọ ni 2024 maa jẹ fun wa - Gomina Kwara fi ọkan awọn araalu balẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 1, 2024

Ọdun aṣeyọri to pọ ni 2024 maa jẹ fun wa - Gomina Kwara fi ọkan awọn araalu balẹ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi ọkan gbogbo araalu balẹ lẹkunrẹrẹ pẹlu ileri wi pe ọdun 2024 yoo jẹ odun aṣeyọri rẹpẹtẹ.

AbdulRazaq lo sọrọ idaniloju yii lakoko to n ki gbogbo araalu ku oriire ajọyọ ọdun tuntun, 2024 ti wọn bọ si.

Nibẹ lo ti parọwa si araalu lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba oun lati mu igbelarugẹ ba awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to n lọ lọwọ, ati awọn eyi ti yoo bẹrẹ lakọtun.

O ni gbogbo ojuṣe to ba yẹ pata ni ijọba yoo ṣe lati rii pe itẹsiwaju n wa ni gbogbo ẹka, paapaa nipa aabo ẹmi ati dukia araalu, titẹle ofin ati ilana, pipese awọn ohun amayedẹrun, ati ṣiṣẹ akanṣe iṣẹ niwọnba owo to n wọle.

O pe awọn ileeṣẹ fun ajọṣepọ to dan mọnran lati le jẹ ki ipinnu ati ileri ijọba wa si imuṣẹ fun araalu.

Bakan naa lo tun pe awọn ọmọ Naijiria lati gbaruku ti ijọba Aarẹ Bọla Tinubu to n fẹ itẹsiwaju fun eto ọrọ aje orileede yii, eyi ti yoo jẹ ki araalu kuro ninu inira bọ sinu igbadun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI