O ṣẹlẹ o! Wọn ji gbajumọ oloye ati awọn mẹta gbe ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 18, 2024

O ṣẹlẹ o! Wọn ji gbajumọ oloye ati awọn mẹta gbe ni Kwara


Ko din ni eeyan mẹrin ọtọọtọ ti awọn ajinigbe ti jigbe salọ nipinlẹ Kwara laipẹ yii, eyi ti oloye ilu naa wa laarin wọn, ti ko si tii sẹni to le sọ pato ibi ti wọn wa, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fidi rẹ mulẹ pe iwadii ti n lọ labẹlẹ.
 
Ẹkun kan ti wọn n pe ni Ile-Ire to wa nijọba ibilẹ Ifẹlodun ni wọn l'awọn ajinigbe ti ji awọn mẹrin naa gbe salọ loru ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ko tii ju wakati bii meloo kan ti awọn aadigunjale yawọ agbegbe Oke-Odo nijọba ibilẹ kan naa, nibi ti wọn ti pa ọkan lara wọn danu ti iṣẹlẹ eyi tun fi waye.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Ejirẹ Adetoun Adeyẹmi, ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe Oloye Simon Ibiwoye to jẹ Olukọtun ti Afin ni wọn jigbe pẹlu awọn ọmọde mẹta miran.
 
O ni Kabiyesi ilu naa lo wa fi iṣẹlẹ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ṣugbọn to sọ pe ikọ ẹṣọ ologun, ọlọpaa ati awọn ọlọdẹ ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati wa gbogbo inu igbo to wa nitosi.

Adeyẹmi jẹ ko di mimọ pe ọwọ ti tẹ awọn mẹta kan ti igbagbọ wa pe awọn lo n ṣe agbodegba f'awọn ajinigbe naa ti wọno ti na papa bora, ati pe foonu wọn to jabọ  ni wọn fi n tọpinpin wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI