O pari! Wọn fi ẹsun ipaniyan kan tọkọ-taya l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 9, 2024

O pari! Wọn fi ẹsun ipaniyan kan tọkọ-taya l'Abẹokuta


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iku ọkunrin kan, Mark Kalu ṣi n jẹ fawọn ara agbegbe Ọdẹda niluu Abẹokuta, sibẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ pe awọn yoo tọpinpin iru iku to pa ọkunrin naa.
 
Ninu atẹjade ti Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun gbe jade, o ni iku Kalu ko ṣẹyin ija ti tọkọ-taya kan, Moses Mba, ẹni aadọta ọdun ati iyawo rẹ, Florence Moses, ẹni ogoji ọdun ba a ja laarin ọja Oṣiẹlẹ.
 
Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ni a gbọ pe ọkọ ati iyawo naa ba Mark ja ninu ọja, ti wọn ti lu ọkunrin naa lalubami.
 
Latigba naa ni wọn sọ pe Kalu ti n gba itọju lọsibitu, ti ara rẹ ko si lelẹ latigba naa, ko to di pe o pada jade laye lọjọ kẹfa, oṣu kinni, ọdun 2024.
 
Gbogbo akitiyan Babalọja Oṣiẹlẹ ati awọn olori ẹya Igbo niluu Oṣiẹlẹ lati yanju aawọ naa ni wọn lo ja si pabo.
 
Ju gbogbo rẹ lọ Odutọla sọ pe awọn ti gbe oku Kalu lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba apapọ, Federal Medical Centre to wa niluu Abẹokuta lati ṣayẹwo lati mọ iru iku to pa a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI