Miracle di àwátì lọ́jọ́ ọdún Kérésìmesì l'Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 4, 2024

Miracle di àwátì lọ́jọ́ ọdún Kérésìmesì l'Abẹ́òkúta


Ọdọmọbinrin ti ẹ n wo yii ni wọn pe orukọ rẹ ni Eloma Miracle, ẹni ti wọn lo di awati niluu Abẹokuta lọjọ ọdun Keresimesi to kọja.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni adugbo Oluwo to wa lagbegbe Kolobo niluu Abẹokuta ni wọn ti kofiri Miracle gbẹyin.

Nnkan bi agogo marun-un irọpẹ ọjọ naa ni wọn sọ pe Miracle dagbere fawọn eeyan wi pe oun fẹẹ lọ luwẹ ninu odo igbalode ti MITROS to wa ni Ibara Housing Estate.

Wọn ni latigba to ti lọ ni ko ti pada sile mọ, bẹẹ ni wọn ko rii pe lori foonu rẹ titi di asiko yii.

Ẹnikẹni to ba kofiri rẹ, ko fi to ileeṣẹ agbofinro leti, tabi ko kan si ẹrọ ibanisọrọ yii 09022614271.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI