Agbẹnusọ fun Alaaji Atiku Abubakar, oludije sipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lọdun 2019, Oloye Ṣẹgun Ṣowunmi ti parọwa si gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lati gbe ipinnu eto idibo ọdun 2027 pamọ lasiko yii, nitori pe kii ṣe nnkan to yẹ ko gbaju mọ lasiko yii niyẹn.
Ṣẹgun Ṣowunmi lo sọrọ yii lasiko to n gba aami ẹyẹ ati oye gẹgẹ bii ‘Akọgun Awọn Oloṣelu’ lorileede Naijiria, eyi ti ileeṣẹ iwe iroyin BOṢERI ṣagbatẹru ẹ laipẹ yii niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Nigba to n sọrọ, Ṣowunmi sọ pe iyalẹnu lo jẹ f’oun nigba toun ri bi awọn ọmọ ẹyin Dapọ Abiọdun ṣe n kọrin ẹni ti ipo gomina kan lọdun 2027, ọdun mẹta si asiko yii.
Ṣẹgun Ṣowunmi sọ pe nigba ti wọn ko tii de lati ile-ẹjọ agba lorileede Naijiria, ti awọn Dapọ Abiọdun ti bẹrẹ sii pariwo ẹni ti yoo gba ipo lọwọ rẹ lọdun 2027.
O ni eyi ku diẹ kaato, nitori pe kii ṣe ohun to yẹ ko kan ree, bi ko ṣe bi yoo ṣe mu ipinlẹ Ogun tẹsiwaju, ti yoo si maa figagbaga pẹlu awọn ipinlẹ ti wọn ti ni idagbasoke.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Mo dupẹ gidigidi fun aami ẹyẹ ti ẹ fun mi yii, mo fi tinutinu gba a pẹlu idunnu to pọ. Bi ko ba si ohun ti ẹ ri, ẹ ko nii ronu lati fun mi ni aami ẹyẹ yii, inu mi si dun wi pe ẹyin kan ri itara ti mo ni fun idagbasoke ipinlẹ Ogun ati orileede Naijiria lapapọ.
“Ọrọ amọran si gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ni pe gomina ti Ọlọrun ba ti fun ni oore ọfẹ lati ṣe saa keji ṣe, Ọlọrun ti fun un ni oore ọfẹ pe ki wọn ma ṣe gbagbe orukọ rẹ titi lai ni. Ẹni to ṣi fẹẹ ṣe saa kan ṣoṣo gan-an ko tii ri.
“Ki ẹni ti Ọlọrun ba wa ti fun ni oore ọfẹ lati de ipo lẹẹkeji naa wa bẹrẹ awọn akanṣe iṣẹ ti yoo ni ipa rere, iyẹn awọn iṣẹ manigbagbe si aarin ilu.
“Ti eeyan ba jokoo lori wi pe oun fẹ maa san owo oṣu nikan, iyẹn kọ ni pe o n ṣiṣẹ, nitori pe to ba kuro nibẹ lọla, awọn to ba debẹ yoo tẹsiwaju lati maa san owo oṣu lọ.
“Ẹlẹẹkeji gẹgẹ bi amọran ni pe, gomina gbọdọ jẹ ki awọn araalu maa ri oun daadaa. Ẹni to ba n ba ọmọ ṣere ni ọmọ maa mọ oju rẹ. A ni anfaani awọn to ti lo ile ijọba to wa ni Oke-Igbein, ṣugbọn gomina yii ko debẹ rara, oju ofurufuru lo ti n fo kaakiri.
“Ẹlẹẹkẹta ni pe ki Gomina Dapọ Abiọdun ma ṣe gba ẹnikẹni laaye lati bẹrẹ ipolongo ọdun 2027 lasiko yii, o ti ya ju. Ori lo mọ ẹni to maa jẹ ọba lọla, ki Ọlọrun ka gbogbo wa mọ wọn.
“A ko tii de lati ile-ẹjọ giga, ti awọn eeyan ti wa n ṣebi ẹni pe awọn fẹẹ dibo ni ọtunla. Ki gomina lọ beere ohun to maa n pada ṣẹlẹ lẹyin iru nnkan bayii lọwọ Ọtunba Gbenga Daniel. Iru ẹ lo ṣẹlẹ lọdun 2007 nigba yẹn.
“Kọla Ọnadipẹ ko tii ku, OGD funra rẹ ṣi wa laye bayii, Kẹhinde Ṣogunlẹ naa ṣi wa laye, gbogbo wọn ni mo sọ fun nigba naa pe ki wọn ṣọra wọn. Wọn ko gbọ si mi lẹnu lọdun naa lọhun, lo jẹ ki ipinlẹ Ogun maa wa ninu awọn iwe iroyin lojoojumọ nigba naa pẹlu ija oriṣiriṣi.
“O yẹ ka ti pari papakọ ofurufu ti wọn ṣẹṣẹ n ṣe yẹn tan tipẹ; iru ibudokọ oju omi ti wọn gbe lọ s’Ekoo, awa lo yẹ ka ti ṣee tipẹ. Ibi ti iwa imọ tara ẹni nikan ba wa de niyẹn.
“Ariwo Yewa lo kan, Ẹgba lo maa ṣe, Ijẹbu lo nii, Rẹmọ lo n bọ ti wọn n pariwo lo jẹ ki radarada maa ba wa lati ọjọ yii. Eyi lo fi di pe iṣẹ to yẹ ka ṣe laarin ọdun 2007 si 2011, a ṣi n ra nidi ẹ titi di asiko yii ni.
“Nigba ti Ibikunle Amosun naa bori ibo ẹlẹẹkeji lọdun 2015, oun tiẹ gbiyanju agbara rẹ, ko jẹ ki wọn pariwo ‘talo kan’ foun nigba yẹn.
“Ẹni to ba fẹ ki ilu oun maa pa owo wọle ni gbogbo igba, o ni lati wa eto ti yoo jẹ k’awọn eeyan maa wa sibẹ ni gbogbo igba ni, ẹ ko le jẹ ki ilu ni alubarika ti awọn eeyan ko ba n lọ sibẹ.”
Ṣaaju asiko yii ni alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ iwe iroyin BOṢERI, Ọgbẹni Jonhson Akinpẹlu nigba to n ṣorọ nipa aami ẹyẹ yii, o ni ogbontarigi olotitọ eeyan ni Ṣẹgun Ṣowunmi jẹ nidi oṣelu.
O ni o wa ninu awọn to fẹran lati maa sọ otitọ ni gbogbo igba, ti kii sii ba ẹnikẹni ja ija, ati pe ọna abayọ si iṣoro to ba n dojukọ ilu ati orileede ni ọkunrin naa maa n wa ni gbogbo igba.
No comments:
Post a Comment