Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti ọba alaye kan n'ipinlẹ Ogun, Ọba Kọlawọle Ṣowẹmimọ to jẹ Olu tiluu Owode nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode ti bẹrẹ sii bẹbẹ kaakiri bayii pẹlu aṣemaṣe to ṣe nita gbangba laipẹ yii.
Ni nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin la gbọ pe ọba alaye naa tapa si ofin orileede Naijiria nipa ṣíṣe owo Naira niṣekuṣe, lai bikita ohun ti yoo tẹyin rẹ yọ.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni olori kabiyesi lo ṣayẹyẹ ọjọ-ibi ọgọta ọdun laipẹ yii, ti ọba alaye naa si ranṣẹ pe gbajugbaja olorin Fuji nni, Wasiu Ayinde ti ọpọ mọ si K1 De Ultimate lato wa kọrin nibẹ.
Nibi ti Wasiu Ayinde ti n kọrin lọwọ ni Ọba Ṣowẹmimọ ti lọ fi owo Naira ṣe okun, to si n na owo ọhun lai bikita.
Beeli, beeli ni Kabiyesi n gbe owo fun Wasiu Ayinde nibi to ti n kọrin, tiyẹn naa si n kii ni mẹsan-mẹwaa.
Fọnran ibi to ti n na owo yii lo jade sori ikanni ayelujara kaakiri, ti awọn ọmọ Naijiria si bẹrẹ sii bu ẹnu atẹ lu Kabiyesi ọhun.
Owo ẹgbẹrun kan naira to wa ni beeli rẹpẹtẹ ni Kabiyesi yii ni na fun Wasiu Ayinde, pẹlu awọn eyi to fi ṣe ẹgba ọrun nla loriṣiriṣi.
Bi fọnran ibi ti Ọba Ṣowẹmimọ ti n ṣe owo naira niṣekuṣe ṣe tẹ ijọba apapọ Naijiria labẹ ileeṣẹ olu-lanilọyẹ ti a mọ si National Orientation Agency (NOA) lọwọ ni wọn ti fiwe ranṣẹ si kabiyesi.
Ninu lẹta ti ajọ NOA fi ranṣẹ si Ọba Ṣowẹmimọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni wọn ti sọ pe iwa to n gbe eeyan de ọgba ẹwọn ni Kabiyesi wu, nitori pe o ku diẹ kaato.
Lẹta naa ti alakoso agba pata fun ajọ NOA, Lanre Issa-Onilu buwọ lu lo ti ni o ṣeni laanu wi pe awọn to yẹ ki wọn maa daabobo ohun idanimọ ati ogo Naijiria ni wọn ṣee baṣubaṣu bo ṣe wu wọn.
Ọba Ṣowẹmimọ nibi to ti n na owo fun K1 |
Ṣugbọn nigba toun naa n sọrọ lori lẹta ti ajọ NOA kọ ranṣẹ sii, Ọba Ṣowẹmimọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun kabamọ iwa toun wu naa, ṣugbọn sibẹ, o loun kọ lẹni akọkọ ti yoo ṣe iru nnkan toun ṣe ni Naijiria.
Kabiyesi jẹ ko di mimọ pe oun yoo yago fun awọn iwa to le doju ogo Naijiria bolẹ lọjọ iwaju.
O ni idunnu ayẹyẹ ọjọ ibi iyawo oun to gba ọkan oun ni ko jẹ koun ronu pe iwa abuku loun hu, ṣugbọn ṣa, o bẹbẹ pe ki ijọba foju aanu wo oun gẹgẹ bi ori ade.
Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi ni “Mi o fẹ jiyan tabi pe ki n ba ẹnikẹni sọrọ ọhun mọ. Ti mo ba ti ṣe ohun to lodi, ẹ fori jin mi. Ọkẹ aimọye fọnran lo wa lori ayelujara to ṣafihan b'awọn eeyan ṣe n na owo, koda ti wọn tun n tẹ owo naira mọlẹ.
“Mo mọ pe wọn kan fa emi yọ laarin wọn nitori pe mo jẹ ori ade ni, mo si ti sọ pe ki wọn ma ṣe binu. Ohun ti wọn sọ ninu lẹta ọhun ko yatọ si pe wọn n gba mi lamọran nitori mo jẹ ọba alaye, ṣugbọn mo fi n da yin loju pe iru rẹ ko tun waye mọ.
“Inu mi ko dun pẹlu bi awọn eeyan ṣe n sọrọ nipa mi lori ayelujara. Mo gbagbe ara mi nitori ayẹye ọjọ ibi iyawo mi. Fun ọun mẹtala, nko ṣayẹyẹ kankan, eyi lo jẹ ki inu mi dun, ti mo si fẹẹ tayọ nibi ayẹyẹ ọhun. Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ẹ fori jin mi.”
No comments:
Post a Comment