Giwa agba ni fasiti iṣẹ agbẹ ati ọgbin, Federal University of Agriculture, Abẹokuta (FUNAAB), Ọjọgbọn Oluṣọla Babatunde Kẹhide ti sọ pe fasiti naa ni ilẹ to too ṣe iṣẹ agbẹ lati bọ gbogbo ilu Abẹokuta.
Ọjọgbọn Kẹhinde nibi FUNAAB ṣe ni ilẹ rẹpẹtẹ to, ko si owo lati fi da gbogbo oko ti yoo bọ ilu Abẹokuta ati agbegbe rẹ lọwọ awọn.
Nibi ipade awọn akọroyin ti fasiti ọhun ṣe, eyi to ṣaaju eto ayẹyẹ ikẹkọọgboye to fẹẹ waye ni fasiti naa lopin ọsẹ yii.
Nibẹ ni Ọjọgbọn Kẹhinde ti sọ pe awọn akẹkọọ ti ko din ni mejilelọgọfa (122) ni wọn wa ni ipele akọkọ, First Class ninu awọn akẹkọọ ẹgbẹrun mẹta ataabọ le diẹ (3,754) to fẹẹ kẹkọọ gboye.
O ni ọpọ awọn ọtọkulu lo n bọ lọjọ naa bii alaga ajọ eleto idibo tẹlẹ lorileede Naijiria, Atahiru Jega ati awọn miran.
Bakan naa lo ni awọon 1,540 ni wọn ṣe daadaa pẹlu ipo keji (Second Class Upper).
Nigba to n sọ nipa awọn adojukọ, Ọjọgbọn Kẹhinde ni awọon ni ilẹ rẹpẹtẹ lati fi da oko, ṣugbọn owo ti yoo da gbogbo oko fun ounjẹ ti yoo bọ Abẹokuta ati agbegbe rẹ ni ko si.
O ni awọn ohun elo bii katakata ti wọn fi n roko ati eyi ti wọn fi n da oko ni agbara wọn ko gbe, ṣugbọn to ni awọn n reti awọn ileeṣẹ aladani ati ajọ to le tọwọ bọwe adehun fun ọpọ ounjẹ lawujọ.
No comments:
Post a Comment